Smiley face

Ise Akoni Adewale Dada TheGood Ti Leke Gbogbo Aye

Wale Dada TheGood
Odun 1729 ni won bi Edmund Burke to je agbaoje onimo ijinle nipa eto ilu ati iselu ni orileede olominira ilu Ireland. Ojo kesan-an osu keje odun 1797 ni akoni yii fi ile aye sile ni eni odun mejidinlaadorin (68yrs). Opolopo awon eniyan lagbaye nigba naa ni won ka iku Edmund Burke si adanu nla latari awon ise akin to ti gbese saaju ki alumuntu to mu lo si ajule orun.



Bakan naa, akosile iwe itan isesi omoniyan ati iseda eleyii ti a ri ni Ifafiti Harvard to wa ni ilu Amerika fi odindin abala oju iwe meji se afihan awon oro akin Edmund Burke eleyii ti ko si anfaani iru e fun awon agbaoje onimo ti won lo sanmooni papo pelu Edmund Burke.  Ninu iwe  yii ni won ti se akosiile oro Edmund Burke kan eleyii to so ni odun 1782. Awon  onwoye si se alaye wi pe bi gbogbo oro Edmund Burke ba tile pare eyi to so lodun 1782 ti doosa ti yoo maa wa titi lailai.


Oro wo ni Edmund Burke so ni odun 1782?


Ni ilu Nigeria, awon eniyan ki i mo riri awon eniyan takuntakun ti won je olotito ayafi ti won ba lo. O se pataki lati ri irufe awon eniyan wonyii gege bi akanda ati ibukun eleyii ti Olorun fi ke wa ki igbiyanju ati ilakaka won maa ba a ja si asan bansa.
TheGood, Eni Olorun ran
Ipinle Ogun ni won ti bi  Adewale Micheal Adegoke Alao omo Dada. O kawe gboye, o se ipo kinni. O sise aje nile yii ati loke okun, o jere tabua. Ogbon atinuda ati ebun ti Oba Oke fi jinki re si ti di okiki nla kari gbogbo agbaye. 

Sugbon lara ero Ogbeni Wale Dada ni wi pe akoni tabi alaseyori tabi asaaju ki i se eniyan to wa igbe aye to rorun fun ara re nikan bikose lati ran awon eniyan lowo ki awon naa le moke ninu igbiyanju won.
O ti san
“Before you are leader, success is all about growing yourself. When you become a leader success is about growing others''
To ba je nipa ka ja fun eto omoniyan, siso okodoro oro lai beru enikeni, fifun awon mekunnu ni ireti ati idunnu ojo ola; ati igbelaruge oruko rere Nigeria, awon nnkan wonyii ni Adewale Dada ti n se bo lati ri daju wi pe igbe aye to dun je ti gbogbo mekunnu pata.
Ojo aboki ti pe ni Sabo. Aimoye odun seyin ni Adewale Dada ti maa n se koriya fun gbogbo mutumuwa nipa sise afihan agbara to wa ninu ireti. Adewale Dada gbagbo wi pe ti a ko ba so ireti wa nu gege bi orileede, dandan ni ki ilu Naija mu oke lagbaye. Eleyii lo mu pupo awon ise TheGood, eto ori redio ati telifisan, ipolongo ati idanileko re kun fun agbara ireti ogo ati iwosan fun ilu olokiki ti won pe ni NIGERIA
Gbogbo ologbon aye le salaye oro to ba ruju. Oniro eda ki i gbayii ni gbogbo igba. Aimoye igba ni awon onibaje ti ni  ki Wale Dada ye so otito mo. Sugbon Alao ki i gbo, oni ti oun ba dake iya to je Moshoodi omo Abiola yoo di iya ajegbe fun iran omo Yoruba lapapo. Bee aimoye igba ni won ti ran janduku si Alao ri, sugbon Edua oke ko pada leyin olododo. 
Yato si eleyii, gbogbo anfaani ti  Adewale Dada ba ni lati ba awon asaaju ile Yoruba soro lo maa n lo lati mu won ranti iku Abiola ati ipo ti awon mekunnu wa. Bakan naa lo maa n so idi pataki to fi ye ki awon omo Yoruba wa nisokan.  Nitori aikoworin omo ejo lo seku pawon, igi kan soso ki i si dagbo se.

Adewale Dada, gbogbo omo Yoruba n dupe fun ise akoni to n se ati iwa omoluabi to n fi n han nigba gbogbo. O seun. 


Nibayii, Adewale Dada ti pinnu lati tele oro ti Edmund Burke so lodun 1782 to wi pe;


 "All that is necessary for the triumph of evil is that good men do nothing."


Igba melo, odun melo ni a fe fi pariwo e tun Nigeria se? Awon ojelu ko won o ronu piwade bee ni won kotiikun si waasu mimo.  Eyi ni die lara nnkan ti Wale Dada ro papo to fi setan lati mu amoran Edmund Burke to so lodun 1782 sa bi ogun.


 "All that is necessary for the triumph of evil is that good men do nothing."
Adewale Dada ti setan lati soju ekun Ota 1 State ni ile igbimo asofin ti Ipinle Ogun ninu eto idibo odun 2015 to n bo lona. Ko si ipo ti eniyan wa ti ko le kopa to joju ninu idagbasoke ilu niwon igba to ba ti je wi pe inu kan ni irufe eni bee fi n sise.

Adura wa ni wi pe ki oba Oluwa ran enirere lowo lati le mu ero re ni rere se fun gbogbo mekunnu. Amin


Olayemi Oniroyin loruko mi. Awon eniyan mi nigboro ni won fi irawo kun irawo mi ti won pe mi ni Oniroyin Agbaye. Lara ero ati igbagbo mi ni wi pe ise iroyin ko yato si ise awo. Babalawo ti ba n paro faye Ifa won ni i pon won laso bi eye igun. Oniroyin ti ba ti n seke oro eniyan yepere bi alagbere niwon jo loju aladugbo.  Eyin ologbon aye e maa kiye soro mi.

O di gba!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

6 comments:

  1. OLORUN YOO RAN LOWO JU BI OUN GAN SE LERO LO. E FILE BEYEN,KOWA BEYEN

    ReplyDelete
  2. my name sake, we believe in you. we love. may almighty Allah help u. amer

    ReplyDelete
  3. wow! WELL DONE ADEWALE DADA OMO OLOTIN OTA. i havw been convinced long time ago that u really love Nigeria. You have been spending ur money, time and talent to promote NIGERIA. GOD BLESS U THE GOODMAN.

    ReplyDelete
  4. Wale omo Dada, Wale the Good ni, eni ti gbogbo ota nfe, n'ile igbimo asofin!

    Asiko to lati fi eni to to, si ipo to to, ko le san fun wa, ki agbegbe ota le wa nipo iwaju. O si maa san, ti a ba le dibo fun Adewale omo Dada.
    E file be yen!

    ReplyDelete
  5. Well done OLAYEMI. U r creative

    ReplyDelete