Aseyori egbe Super Eagles ile Nigeria gege bi iko agbaboolu to se ipo keji ni isori F ti idije boolu agbaye to n lo lowo ni ilu Brazil ti mu won je egbe agbaboolu ile adulawo akoko ti yoo kopa fun igba meta ninu abala keji (2nd Round) idije boolu agbaye FIFA.
Bi won se n ko oruko Super Eagle naa ni won ko oruko olukoni agba egbe naa, Stephen Keshi gege bi olukoni adulawo akoko ti yoo ko egbe agbaboolu wo abala keji idije boolu agbaye FIFA.
Aseyori yii ni awon onwoye ere idaraya ile adulawo ri gege bi aseyori to laamilaaka fun ile Nigeria.
Ninu idije boolu agbaye to n lo lowo, asoju ile adulawo meji lo seku ninu idije naa; Nigeria ati Algeria.
Ile Nigeria yoo maa ta tan pelu France ni ogbon ojo osu taa wa yii nigba ti Algeria yoo ma ja gidigbo ori papa pelu Germany.
Keshi ti so nipa ipo won ninu idije naa ati idi pataki to fi ye ki won tun mura daada sii.
"We are the African champions and have a collective responsibility to not only play for our country, but also the continent." Keshi.
Joseph Yobo to je Balogun Super Eagles naa soro, e gbo ohun ti won so.
"We have achieved our first goal of
reaching the second round.
"Now we must forge ahead to ensure our continent gets the best representation in Brazil."
Olayemi Oniroyin Agbaye, ilu Brazil ni mo ti lo mu iroyin eyi wa.
E ku faaji opin ose.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment