Jeje ni mo joko sile mi ni irole ana ni ago gasimileti mi ba dun. Nomba lasan lo gbe jade, ko gbe oruko jade.
Oju ese ni okan mi ti n so fun mi wi pe o le je okan lara awon ololufe wa ti won ka Olayemi Oniroyin. Igba ti maa pada gbe foonu naa, bi mo se ro gele bee naa lori.
Isorongbesi to waye laaarin awa mejeeji ni yii.
OO: Eloo
KM: Eloo. E kurole o. E dakun se Olayemi Oniroyin ni mo ba soro? (ede Ilorin ni okunrin naa fi n soro)
OO: Awa ni o. E joo, kini mo le se fun yin o?
KM: E seun. en...en...Kasali Morufu looko mi lati ilu Oshogbo. Sugbon e le pe mi ni Alfa Moffy. E dakun, tiyin o ni baje kiakia. Olorun o ba n wo ola inu osu alaponle ta a fe wo yii koni je ke e ko sinu panpe obirin.
Mr Olayemi, e moo samin bi mo se n fun yin ladua un fa. Ori awo ni mo wa bayiibayii. Akanse adua kan ni mo n se lowo ni mo fi ni ki n sare pe yin.
[Bo se n soro ni mo n samin tele]
Iroyin ti o tenu yin jade ti won o fi ni ke e wa ro tenu yin ni kootu, Satiramoni ko ni je o tenu yin jade.
[Mo ti koko fe ja call naa danu, mo kan tun daro ni. Abi e wa gbo awon adura radarada to n se ni; ' ti yin o ni baje kiakia'.?]
OO: Amin.....Amin.
KM: Mr Olayemi, A mo gbadun yin o. Walahitalahi mo mo n gbadun yin gan-an ni fa. Awon iroyin te e mo n ju sori afefe mo n wa OK gidi gan-an ni.
Paapa iroyin omoge onibadi olokiki ilu Amerika te e mo n mu wa fu wa un. Mo ti n ri ibadi laye mi, ibadi omobirin onibadi olokiki naa tun ja mi laya pupo.
Ki Ibadi ri gelete bi aso okirika ti won di sinu sakasaka. O tun wa le lowo bi apo simenti Dangote. Apa otun ati apa osi ibadi re wa yogun bi ile tiiro. E leyii tun wondafu!
OO: A bi o. Talent onikaluku otooto ni.
KM: O daa. Se e ri, Pataki oro mi gan-an ti me e pe yin gan-an ni nipa omobirin onibadi olokiki ilu Amerika un.
OO: Se Kim Kardashian?
KM: Han-in. Oun naa ni. E dakun e ba wa wi fun ko gbe ibadi re pamo di eyin awe ramadan.
Nitori ara mi tete mo n muufu ti n ba wo ibadi re. Mi o si ni fe nnkan ti o mo ja mi laawe.
Emi gan-an ti seleri wi pe gbogbo foto re to wa lori foonu mi ni maa delete patapata, sugbon kii se nii sinyii sha ni maa delete e, ale ojo ti a ba ki asamu ni maa delete gbogbo e.
Bakan naa, ke e si so fun gbogbo awon omo alaso esubeleke ti won kungboro ki won saanu mi ki won o je ki awe mi o pe lodun yii.
Nitori igba awe ni karabiliti won mo n lo soke si. Awon omo oloso, omo ale gbogbo. Gbogbo aya ni won o ko soke ti o wa ta sita bokua bi isu Abuja. Ohun ti mo ni ki n so fun yin na nu-un ni.
OO: OK o! Ko si wahala, gbogbo ise te e ran mi pata ni maa je.
KM: O daa baun. E si mo gbagba alaye nipa Sunday Igboho te n ba lo.
OO: E maa worry. Gbogbo re naa la o se.
KM: O dabo
OO : O dabo oo.
0 comments:
Post a Comment