Awon Yoruba ni bi onirefin ko ba fingba mo, eyi to ti fin
sile ko le parun lailai. Funmi Iyanda le maa foju han lori mohunmaworan
bi ti igba kan mo, sugbon ise akoni to ti se seyin ni o maa jeri re gege
bi oniroyin to dangajia.
Omo Ogbomosho ni Funmi,
Ifafiti ijoba apapo to wa ni ilu Ibadan lo si ti kawe jade. Eto re ori
telifisan apapo si wa lara awon eto to migboro titi ni awon akoko ti eto
naa fi wa lori afefe.
Ilu Amerika ni Funmi wa bayii.
Funmi kosi nile oko fun igba pipe seyin sugbon oni omobirin kan eleyii
ti ko le se lai ma menuba nigba gbogbo nipa ife to ni si omo naa. Funmi
Iyanda je oniroyin to maa n se iwadii finifini lori akanse ise to ba gbe
dani. O si maa n sise lai wo oju ago.
Tunde Kelani se apejuwe re gege bi 'AJE' - Ogbologbo Aje Oniroyin.
Oniroyin
bi Funmi ko pe meji ni ilu Nigeria. Awon to fe dabi re si n le ni, won
ko tii ba. Mo peri akoni lonii, mo si fida mi hale gaaaraga.
#Ogbontarigi
0 comments:
Post a Comment