![]() |
Aye Mi |
Orisiirisii aditu ogbon lati ri ni owo awon onimo agbaye,
onise alakada ati awon onwoye nipa igbe aye awon eniyan lawujo. Lara iru akiyesi ogbon naa ni wi pe
opolo ti Edumare fun eda eniyan kii baje raurau- ki i ba je ise aye tabi
afowofa ara eni. A ri apeere eyi nipa wi pe ko si bi were se ya
digbolugi to, to ba ri moto ti n bo n se ni o sare yago lona. Abala kan ninu opolo won si n sise lati se akiyesi ewu tabi ijamba.
Bibeli
naa salaye orisii were kan eleyii to bugije koja apejuwe. Iboji ni were
naa n gbe; o si maa n fi okuta ya batani si ara re lopolopo igba. Sugbon lojo kan o
ri Jesu, opolo re si so fun wi pe Jesu lori. Awon onimo oro Olorun (Theologist) si je ko ye wa wi pe oseese ki okunrin naa ti gbo
nipa Jesu ri nibi kan idi ni yii to fi sare too Omo Maria wa fun igbala.
E maa ro wi pe ki lo fa surutu repete? 'Oga oniroyin e fitan sile, koko la fe gbo.'
O daa, ko buru, mo ti fe e debi ti mo n lo. Sugbon sa, e ma gbagbe wi pe mo n so nipa aditu ogbon eleyii ti awon onwoye se akiyesi re ninu iseda eniyan lawujo.
E tun gbo eleyii...
Nigba
lailai, awon agbalagba Yoruba aye atijo gba wi pe laakaye to je baba ogbon a maa ya inu
awon omode (tabi awon odo) sun leekookan tayo ohun ti agbalagba le ri kojo fun odindi ogorun odun. Idi ni yii ti won fi n pa owe wi pe omode gbon, agba gbon ni won
fi da United Kingdom. Ha! E ma binu, Ile Ife ni mo fe wi. Omode gbon, agba gbon la
fi da Ile Ife.
Leyin igba ti mo ti salaye ero okan mi. E je ka pada sori afihan fiimu wa fun osu yii, eleyii ti won pe akole re ni AYE MI lati owo Bose Oladimeji (Alubarika). Ojo ori ko ni ohunkohun se pelu ogbon ori. Eni wu Edumare ni
oba mi oke n fun ni laakaye yanturu. Bi eniyan ba buru to si daju bi alujannu ti
won pe ni Sani Abacha tabi Idi Amin ti ilu Uganda, bi eni naa ba wo Omo Orukan ti Adebayo Salami
se, dandan ni ko yomi loju. Bee, omode ni Bayo lodun to fi ogbon ori gbe
itan naa kale. Muyiwa Ademola ti salaye ri wi pe fiimu ORI ti gbogbo aye
n pariwo, okan ninu awon itan ti oun ti ko nigba ti oun wa ni ile iwe
girama ni.
Mo ti pinnu wi pe mi o ni so ohunkohun nipa
fiimu AYE MI to ti gori igba titi di akoko ti o fi gba ami eye. Enikeni ti e ba ti ri, e bere lowo won wi
pe se won ti wo fiimu naa. Ohun ti won ba ti wi ni kee tele. Bi o tile je wi pe Bose Alubarika ti se awon fiimu kan saaju, sugbon itan Aye Mi ti wa lowo re tipetipe eleyii to se Afeez Eniola ni kayeefi lojo ti Bose Alubarika mu akosile itan naa jade sita. Muyiwa Ademola ri agbekale itan naa lo fi gba lati kopa ninu re. Awon agba osere yii gbimopo, won si gba wi pe ki Bayo Tijani dari ere naa latari iriri ati awon aseyori to ti ni lori awon fiimu onirawo meje bi ti Aye Mi to ti dari seyin.
Ibo ni Bose Alubarika ti ri ogbon ko iru itan yii?
Eni to beere oro lo fe idi re gbo. Eni to fe ori ahun ati ese ahun, dandan ni ko ra odindin ahun. Bayo Tijani lodari fiimu tuntun yii, Afeez Eniola ni alamojuto. Lara awon osere fiimu naa ni Bimbo Akintola ati Doris Simeon, sugbon maa royin ki e kiyesi Arike Akinyanju pupo. Alubarika ti wo ise owo Bose Oladimeji ni
Almaroof se n ta kiri aye. Alubarika ko ni won ninu ise gbogbo wa. Amin.
![]() |
Bose Oladimeji (Alubarika) |
![]() |
Aye mi o! Se ki n se Arike ni mo wo yii ni? Walahi, n so fun moomi ti n ba dele. Chai!!! |
0 comments:
Post a Comment