Smiley face

Ilu Tuntun Labe Orun


Awọn onimọadayeba ati ọlaju-aye-atiju (Anthropology civilization Expert) ti bẹrẹ isẹ iwadii to gbona ribiribi nipa ayipada ti o ti de ba awujọ wa eyi ti ọpọlọpọ wa ko fura si.

Abọ (report) pupo ninu alaye won si ti n di mimọ diẹdiẹ fun gbogbo araye. Sebi airinjina lairi abuke ọkere, bi eniyan ba rin jina ni o ri bi ti won tin fodo ibile jẹun.

Iwadii fi ye ni wi pe ilu tuntun kan ti lalẹ wu labẹ ọrun yii. Kayefi lo si je fun gbogbo ọlọgbọn aye wi pe kosi eni to le so ibi ti ilu yii farasin si saaju awon asiko yii, ko to wa di wi pe awon onise iwadii kan-an nibi to wa loriilẹ aye.

Lọwọlọwọ bi a se n soro yii, bi eniyan tilẹ wo inu aworan atẹ agbaye ko le ri ilu yii nibe.

Sibẹsibẹ ilu yii mbẹ labẹ orun.


Iyanu ni eyi jẹ lati gbọ nipa ohun ọtun to de ba orile aye. Eyi si tun jẹ apẹrẹ itesiwaju imọ ti o de ba awon asewadii agbaye ti won ko fi igba Kankan duro si oju kan bi adagun odò.

Ohun ti o jọni loju ju ni wi pe aimoye orisiirisii eya (nationality) lo parapọ lati tẹdo sinu ilu tuntun yii. Awon ẹya yii wa lati orisiirisii ilu kaakiri agbaye, bi ilu Jamani, Amerika, ilu Oba, Ijibiiti, Ilu olominira Kongo, Ilu aganyin, Ile Saro, ilu Arilandi ati awon ilu mii kaakiri agbaye. Ninu awon ilu naa la ti ri ilu olokiki nla nii ti a mọ si Naijiria ati ilu mii bi China, Japan Saudi Arabia naa o gbeyin nibe.

Bi o tile je wi pe oniruuru ẹya ni won je, ti ede Taye si yatọ si ti Kehinde. Sugbon orisii ede kan ni gbogbo won yan laayo lati ma so ninu ilu tuntun ti won da silẹ yii.

Mo mo wi pe e ti maa bere ninu okan yii wi pe iru ede wo ni won yan laayo, ati wi pe ibo ni ilu naa wa gan-an? Kini oruko ilu to kun fun iyanu ti a n sọrọ rẹ yii?

Boko ko jina, ila ki i ko. Ẹni a si n gbe iyawo bọ wa ba, won ni ki i gbe ori iganan woran.

Ọpọlọ lo ni bi won ba n gbe iyawo tuntun, oun ki sure lọ re woju iyawo. Oni nitori wi pe ko to to osu meji, iyawo fun rara rẹ ni o wa gbe ara re wa ba oun lódò, koda ni o tun bora fun oun ni ihoho.

Ko to di wi pe a dahun awon ibeere ti n tawọtasẹ ninu yin. E je a sọ die nipa awon eniyan inu ilu yii siwaju si.

Fun igba akọkọ, a ri isowo awon eniyan ti won ko ara won jọ fun ilosiwaju enikeji won laiwo ti ẹlẹyamẹya, lai wo esin, ipo tabi ọjọ ori, tabi ohunkohunkan to le fe jẹ adina fun emi ifẹ ọkan won

Enikankan ki i se ibajẹ enikankan.

Bi enikan ba n gbinyaju atimoke, gbogbo a ra ilu ni won ran eni bee lowo. Bi enikan ba ni oun ko ni ise lowo, gbogbo ilu ni won ma ba iru eni be foju sode, bi won ba ri anfaani ise to le mere wa, won fi lo ara ilu won ki oun naa le je eniyan lawujo.

Gbogbo awon ara ilu yii pata lo je omoluabi ati eniyan pataki lawujo.Eyi to n se ise olopa ninu won ki i gba riba. Omo ile iwe ibe ki i jiwe wo ko to yege. Eyi to je iyawo ile n se itoju ile re ati oko re nigba gbogbo. Awon odo ilu yii ki i wu iwa eeri. Atagba atomode pata ni gbogbo iwa owo (hand) won wuni bi wura ati fadaka.

Asa ati ise won ti won n gbe laruge lo je bi akomona fun gbogbo eniyan gbogbo. A si tun gbo wi pe opolopo awon eniyan agbaye si ti setan lati ma ko nipa asa ati ise won.

Awon eniyan yii joni loju de ibi wi pe won ko ni ede eebu ninu ede ti won yan laayo lati ma so. Won ko ti le mo ohun tin je eebu.
Won kii ja. Bi ebi kan soso ni gbogbo won jon se.Gbogbo igba ni won ma n jiroro nipa ohun to dara ati ohun ti o le mu itesiwaju ba iran eniyan lapapo.

Ologbon niwon bee oye ye won pupo lapoju. Ati le gbo wi pe opolopo won tile le kaweju. Bee arojinle won tayo teeyan lasan, eyi lo tunbo je ki oro ilu yii maa seni ni kayefi.

Iru ilu wo le yii? A bi paradise ti sokale si ode aye yi? Bi paradise ba sokale si ode aye, sebi gbogbo aye ni o mo nipa re lowo kan.Sugbon gbogbo eniyan agbaye ko lo ti mo nipa ilu tuntun ti a n soro re yii. Koda, eyi ni atejade akoko nipa ilu naa.

Ilu ti kosi ekun, ilu t ikosi ose. Ilu alayoti o je wi pe gbogbo igba ni awon omo ilu yii maa n pe ara ita wa ki won wa bula ninu ayo ati idunnu ti o wa ninu ilu naa.

Kosi bi iwa eniyan ti buru to, kete ti o ba wo ilu yii, iwa re yoo yipada. Nitori wi pe ni o mo nipa ohun ti n je omoluabi ati ohun ti won pe ni ife alailodiwon.

Mo wi pe gbogbo ara wa nio ti ma re galigali lati mo nipa ilu yii.
Ohun ti o joni loju ni wi pe, bi o se je wi pe aimoye orisii eya lo pe si inu ilu yii gege bi a se so siwaju, sibe won pawopo yan ede Yoruba laayo gege bi ede ajumoso.

Ede Yoruba ni gbogbo won fi ontelu.

Oruko ilu yii ni a gbo wi pe o un je “Yoruba Dun”. Ilu ti ko si oga, ilu ti ko si omo ise, ilu ti o je wi pe bakan naa ni gbogbo won ri ti won si n bu ola fun ara won nigba gbogbo.Omode n pon agba le, agba naa bu owo (respect) tomode fun laaye tie.

Yoruba Dun, ilu to n san fun wara ati oyin. Omode wo inu re, inu re dun. Agba wo inu ilu yii, inu re dun. Ati okunrin ati obinrin to wo inu ilu yii ni won lo n dun bi oyin.

Yoruba Dun…Yoo maa dun ni ko ni kan.

Eyin naa le dara po mo ilu naa NIBI
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment