![]() |
Omowe Oluwole Adesina |
Olayemi oba akewi
Mo ri akinkanju mo morin senu
Emi ralabo ide eda mo da ewi le
Emi ri omowe ti n dako ogbon
Mo sopa sakerengbe oro mo fe pede ayo
Omowe Adesina maa gbo
Emi setan mo fe sin gbere ewi atata soju re
Omowe l’Oluwole omo Adesina
A fi kokoro ogbon lura kiri bi ajere
Okunrin kan rogodidi a si kete imo dekun
Adagun omi ogbon ti gbogbo aye n pon n mu
Olugbala onise alakada ti gbogbo eniyan n kepe
Oloju babalawo to le difa nibi opon ifa ti gbe fo
Oloju eyi tole gbeyinkule moye odu to wu
Oloju oloogun tole soko abiku
Oloju alawo dudu to le mefun dani niwaju alawo funfun
Omo Adesina peregede lawa se n pe loosa imo
Omowe l’Oluwole omo Adesina looto
0 comments:
Post a Comment