Ninu oro tuntun lati enu Aare Muhammadu Buhari, baba yii so wi pe ohun to ye to si mu ogbon dani gege bi oloselu ni ki awon eniyan ti won on gbe ni apa agbegbe ti won ti dibo fun oun je anfaani ijoba oun ju ti awon ti ko dibo fun oun rara lo.
Sugbon sa, iwe ofin ile Nigeria ko le gba oun laaye lati se bee.
Leyin oro Buhari, opolopo awon onwoye nipa oro-oselu ni oro Buhari ti n ko lominu; ti won si n so wi pe ko ye fun eni ti a pe ni olori tabi asaaju maa ni iru ero bee lokan. Sebi ore gbogbo ara ilu lo ye ki asaaju rere je lai ni olodi kankan?
Ti e ko ba gbagbe, ninu esi eto idibo Aare odun 2015, Muhammadu Buhari wole ni ipinle mokanlelogun (21) ninu ipinle merindinlogoji (36) nigba ti Jonathan ko ipinle meedogun (15) pelu ilu Abuja dani leyin eto idibo naa.
Apapo nomba ibo Buhari je 15,416,221 nigba ti Oga Jona je 12,853,162.
Kini eyin fe so nipa oro Buhari? Se bee lo se ye ko ri ni a bi beeko?
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment