![]() |
Oku sun ni Ipinle Borno ni Ojoru to koja yii |
Lara ogun to n ja ile Naijeria lati ojo to ti pe ni Ogun Ko-si-ina-monamona, eleyii to to n se akoba fun aimoye eto oro-aje ile wa to denu kole bi ewe igi ope to ti wowe.
Bi opolopo awon eniyan se n so ireti nu boya ni ile Naijaria le bo lowo abiku ina elentiriki ti n yo ilu naa lenu lati ojo to ti pe, iru ero bee tun ti fe ma jeyo boya ni ijoba apapo le segun awon omo iko Boko Haram ti won ti di egungun eja si Naijeria lorun.
Awon omo Boko Haram tun ti kolu agbegbe kan ti n je Banki to wa ni Ijoba Ibile Bama ni oru Ojoru (Wednesday) to koja yii ni nnkan bi ago meji oru (2am).
Won pa olopa, won pa omode, won pa iya arugbo ti n fi opa rin, aimoye awon eniyan ni won pa ni ipakupa ni agbegbe naa eleyii ti enikenii ko ti le so iye eniyan ti o ba isele naa rin.
Komisanna awon olopa ni Ipinle Borno, Lawan Tanko ti jeri si isele buruku yii.
Isele yii ni eleekeji ti yoo waye ninu ose yii. Akoko iru e ni eyi to waye ni ojo ayajo ojoibi ojise nla Muhammed (SAW) ni ojo Isegun to koja nibi ti awon eniyan bi mokandilogbon ti ku iku saara saarin oja latari ado oloro to dun gbamu lojiji.
![]() |
Isele to sele lojo Isegun to koja laaarin oja nibi ti ado oloro ti pa aimoye awon eniyan ti won wa ohun ti won yoo je kiri. |
0 comments:
Post a Comment