Akosile iwe mimo salaye wi pe pataki iwasaye Jesu Kristi ni lati tu orun apaadi ka ki ijoba Olorun si di pupo sii.
Asamo oro yii fe jo ti awon egbe ti won ko ara won jo lati di okan soso egbe oselu ti a mo si APC. A ti igba ti egbe APC ti wa saye ni oniruuru awon eniyan ti n fi egbe PDP sile bo sinu egbe oselu tuntun APC.
Oro ko tun yato rara pelu Ipinle Bayelsa to je Ipinle Aare Goodluck Ebele Jonathan nigba ti awon to sun mo Gomina Seriake Dickson ti Ipinle Bayelsa bi isan orun se binu so wi pe awon ki i se omo PDP mo ti won si teri wo inu egbe APC.
Koda, olori alaabo oludamoran fun Gomina Timipre Sylva ti Ipinle naa tele, oloye Chief Richard Kpodo ni alaga egbe APC Ipinle naa bayii. Nigba ti ogbeni Godwin Sidi to je olori awon odo egbe PDP fun Guusu Ile Naijeria ti je akowe egbe APC fun Ipinle Bayelsa ni tile-toko.
Aimoye awon oludamoran, komisanna ti won mbe labe Gomina Dickson ni won ti dagbere fun egbe PDP bayii pelu ede Eko ti won fi n dasa fun Gomina Dickson wi pe "maa kede kede maa ri e later kede kee". Erkk
Awon Komisanna ati Oludamoran nikan ko ni won fi egbe PDP sile, alaga ijoba ibile Southern Ijaw, Ogbeni Timipa Orunemigha naa fi egbe sile lai so asotele fun enikeni.
Bi o tile je wi pe ko si ohun ti n je egbe APC tele ni Ipinle Bayelsa, awon wonyii ti pinnu lati fi egbe naa lole ninu ose tuntun taa wa yii.
#FiimuToGunGan-an#
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment