Omobirin yii ko si ni ibi ti n sun koja ori akitan ati abe ganta awon oloja to ba ti palemo lale lo.
Omobirin to pe oruko ara re ni Amudatulahi to tun ni oun je omo ilu Ibadan ni awon eniyan sadeede ri ti ikun re bere si ni i ga. Sugbon onira fun awon eniyan lati gba wi pe oyun lowa nikun Amudatulahi, opo awon eniyan sebi iju ni.
Sugbon lojo odun keresimesi to koja yii ni Amudatulahi bere si ni robi eleyii to pada bimo . Bi o tile je wi pe awon eniyan agbegbe naa gbiyanju lati gbe Amuda lo si osibitu sugbon o ko jale. O ri akitan ni ita gbangba ti n gbe naa lo pada bimo si ki awon abiamo to sun mo lati se itoju re gege bo ti to ati bo ti ye.
Nikete ti omobirin were naa bimo ni awon ara agbegbe naa so omo re loruko. Mariam Olorundamilare Odunayo ni oruko ti won fun omobirin jojolo naa.
Bakan naa ni onikaluku lo n mu ohun ti won ni jade lati fi ran iya olomo tuntun lowo fun itoju ara re ati eje orun to wa saye.
Alhaji Babatunde Shittu to je okan lara awon olori agbegbe naa salaye wi pe bi o tile je wi pe enikan pe sori ago eleyii to se alaye ara re wi pe oun ni egbon Amuda, ati wi pe oun bo lati wa se itoju Amuda ki oun si mu pada lo si ilu Ibadan. Alhaji yii salaye wi pe ko si aridaju otito nipa wi pe awon eniyan re yoo toju.
Alhaji Babatunde Shittu wa n ro ijoba lati ba won dasi oro Amuda nipa itoju re ati omo tuntun. Gege bi oro Alh Shittu, won ni bi a ba ni ki were se oku iya re bo ti fe, o le sun je. Yala ko fi iru oku bee se asun tabi suya alata suesue.
Gege bi noosi adugbo ti won kesi nigba ti Amuda n robi lati ba won ge ibi omo se so. Oni bi o tile je wi pe Amudatulahi ni aaganna oni sibesibe ara re si le pada ya ti o ba ri itoju toye.
Awon oniroyin fi oro wa Amudatulahi lenu wo nipa idunnu re nipa omo to bi. E gbo ohun to so.
"Inu mi dun gidi gan ni o. Mo mo wi pe temi o ni gbe ni ilu Eko yii. Ayo mi kun mo si mo pe ayo mi o le tan."
Nibi Amuda ti n so eleyii lowo lo tun pariwo mo enikan legbe re wi pe ko ba oun mu iwe ile oun. Awon oro re yoku ko si tun ba aye mu mo.
>>>>>
Niwon igba ti ile ba ti n su ti ojumo si n mo, orisiirisii isele la o maa ri. Sugbon ibere kan mbe lokan mi ti mi o reni dami lohun.
Talo fun Amudatulahi loyun?
0 comments:
Post a Comment