Smiley face

Oogun Abenugongo Niwaju Banki Ile Ifowopamo


Enikeni ko le so irufe eniyan kan pato to se iru ise bee. Boya awon osise banki naa tinu n bi ni tabi awon onibara ti banki naa ti te oju won mole?

Sugbon ohun to sele laaro ana ojo Aje ni wi pe awon osise banki ile ifowopamo ti First Bank to wa ni Uyo ni Ipinle Akwa Ibom ko to eru ti wo inu baanki pelu ogun abenugongo ti won fi paale si enu ona banki naa


Banki yii kan naa la tun gbo wi pe onibara re poju lo ni gbogbo agbegbe naa karikari..

Awon kan ni ki won lo kesi awon agbofinro ti ise olopa ye daada. Won ni olopa to ba ni sensi lo le yanju oro ti mbe nile yii. Igba ti awon olopa de pelu aso dudu pelu ibon sakabula oloju meji, n se ni gbogbo won faditi ti won takete bi eni wi pe abata ko ba odo tan nigba ti won ri enu ile ti won n ri enu oko.

Oga olopa to saaju iko awon olopa naa salaye wi pe ise aye ni eleyii, eleyii koja oro niso-ni-tesan ati wetin-you-carry to je pataki ise tawon.

Titi di akoko yii, enikeni ko ti le wo inu banki naa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

2 comments:

  1. yusuff sheriffdeen7 January 2014 at 09:29

    Nigba ti mo ri eyi oyamilenu bee si ni erin si pami,amoran temi nipe eje ki won lo pe olori alawo won ti agbegbe naa tabi abore ki won le bawon yanju isoro naa

    ReplyDelete
  2. Eyi tun gontio. O si le je wi pe kii se ogun gidi to je wi won kan fe fi deru ba won lasan.

    ReplyDelete