Orisa Aje Ti Ba Alh Aliko Dangote Mule
Ninu atejade tuntun to jade eleyii ti alaye re kun fofo bi ataare ni won ti se afihan $9.2billion gege bi iye owo to wole sinu apo Alh Aliko Dangote ninu odun 2013 gege ere okoowo re. Apapo owo re wa n lo si nnkan bi ogbon bilionu owo dola ile Amerika ($30billion).
Won kii ba yinmiyinmi du imi, to ba je ti kunkunshi baba owo, Aliko Dangote naa si ni eniyan dudu to lowo ju lagbaye. Nigba to wa ni akaso ogbon ninu apapo awon olowo aye (30th richest person in the world).
Nigba ti Dangote n le iwaju ni ile Afirika, Bill Gates tun ti pada joko remuremu lori aga olowo aye to ni owo ju lo lagbaye pelu bi owo to wole fun ile ise re lodun 2013 se je $524 billion. Apapo owo Bill Gates wa n lo si nnkan bi $3.7 trillion leyin igba ti 2013 kogba wole.
0 comments:
Post a Comment