Smiley face

Ori Pada So Abimbola Otusanya Di Oniroyin Agbaye

Ibi ori n gbe ni i re laye, eda o ni tase ona rara. Ohun to se pataki ni ki onikaluku gbagbo ninu ara ti Eledumare fi sinu koowa wa. Bi o ti wu ko pe to, akosile Olorun fun igbe aye enikookan ko ni tase ona. Oba oke nikan lo si mo igba to dara ju lati mu ogo eda jade. 

Ki ni won pe aseyori tabi alaseyori? Aseyori ni wi wa si aye lati se ohun to ye ki eda se ( ohun ti ori ran ni waye wa se) fun idagbasoke awujo ati itesiwaju iran omoniyan.

Apileko isale yii ni mo ri lori ate Facebook Abimbola Otusanya.

Oruko mi ni Abimbola Otusanya. A bi mi laarin igba ti ile wa Naijiria ti jagun abele tan, si asiko ti omiyale sele niluu'Badan, lojo ojoun. Mo lo sile iwe alakoobere ati girama nilu Ibadan. Mo gbiyanju kawe gboye ni fasiti ijoba Apapo to wa ni ilu Ilorin. Mo gba oye imo ijinle ninu eko Ede Yoruba lodun 2001. Mo si je omo orile ede rere, nitori ti mo sin ile baba mi ni ipinle Gombe lodun 2002. 



Odidi odun meje ni mo fi je oluko Ede Yoruba lawon ile iwe girama meta kan ni ilu Ibadan. Iyen laaarin odun 2003 si odun 2010. Odun 2010 yii, ni mo tataporo bo si idi ise igbohunsafefe, tii se ife mi akoko, gege bi sorosoro lori Ero Radio. Bi o tile je pe a ko fi ijinle ede Yoruba to mi dagba. Lati igba ewe ni mo ti nifee lati maa ka awon iwe itan aroso lede Yoruba ati Geesi. Mo ranti pe n ko ti ju omo odun mejila si metala ti mo ti n da ra iwe apileko awon onkowe to danto, bii Alagba Oladejo Okediji, Alagba Kola Akinlade ati Alagba Afolabi Olabimtan. Ati awon onkowe igbaa ni miiran, ti won mu ede Yoruba wun'ni. Se emi kuku n ka won lasan ni, n o mo pe Adedaa n to mi nipa ona ti n o rin, ti n o fi je eeyan laye! 



Mo gbiyanju lati ko eko nipa imo isiro owo, Amo sa, aini imo isiro Nile iwe girama ko je. Igba ti mo rin gberegbere titi, mo ja ona ti Ori mi fe ki n to. Mo si lo kekoo gboye nipa imo eko Ede Yoruba. Bi o tile je pe, o wun mi lati je akosemose onimo isegun oyinbo nigba ti mo wa ni kekere. Sibe, mo n wi lonii, pe ise ori ran mi ni mo n se! 



Ise igbohunsafefe wun mi, o wun Eledaa mi. Mo dupe pe mo nifee ise ti mo yan laayo! Mo ti de o! Amo n o tii de! Mo sese n mu eye bo lapo ni. Nitori ti eni to mo'mi mo pe ARA si n be ninu mi ti mo fe da! Eyin, e sa ti gba mi gbo, ki e si mo pe, asese-yo-ogomo mi ni eyi! Eyin e te'ti leko, ki e wa maa wo ara ti Eledua fe fi mi da!. Se awon baba mo'ni mo'ni, won wi pe, Eni ba ma a ga, ese re a tiirin! Ani se e wo omode yii daadaa, o sese n mu eye bo la'po ni!


Lati ori Facebook Abimbola Otusanya.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment