Smiley face

Awon Omo Ile Iwe Ti Ilekun Mo Gomina Ipinle Oyo


Fun odindi wakati kan ni awon omo ile iwe Oyo State School of Hygiene to wa ni Eleyele ni ilu Ibadan fi taku senu ona gomina Ipinle Oyo lana ojo Aje nibi ti won ti n fi ehonu won han nipa bi ijoba ko se kobi-ara si idagbasoke ile iwe naa..
 
Gege bi olori awon akekoo ile iwe naa se so, Ogbeni Tunde Ayuba oni lati nnkan bi odun 1933 ti won ti da ile iwe naa sile, aimoye eko ti won nnko nibe ni won ko ti fi onte lu, ati opolopo nnkan amayederun ni ko si ni ile iwe naa rara nigba to si je wi pe owo goboi ni awon san fun ijoba gege owo ile iwe.
 
 
Akowe ijoba Ipinle Oyo, Ogbeni Ismail Alli lo pada yoju si awon omo ile iwe naa o si se ileri wi pe ijoba ko ni sun gbagbe lori oro ile iwe won ati wi pe ijoba Ajimobbi ni eto to gbamuse fun eto eko Ipinle Oyo eleyii ti won ko ni pe maa ri awon ise iyanu naa lorisiirisii.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment