Smiley face

Awon Soja Sare Kabakaba Nigba Ti Won Ri Boko Haram Ni Maiduguri


Lojo Aiku to koja yii ni awon omo Boko Haram tun ya wo agbagbe Mafa to wa ni Ijoba Ibile Mafa ni ilu Maiduguri nibi ti won ti bere si ni dana sun ile awon eniyan. Ibi won ti n se ise ibi yii ni awon omo ologun Naijeria ka won won mo ti oro naa si di isu ata yan-anyan laarain Boko Haram ati awon omo ologun ti won jo n tuto ija si ara won loju.
 
 
Gege bi oro awon agba, won ni ibi ti erin meji ba ti n ja, koriko ibe ni yoo je pupo ninu iya ibe. Awon ara ilu bi mejilelogbon ni won ba isele naa lo ti won si ti pada sin won lojo Aje ana yii.
 
Gege bi Senato Ahmed Zannah ti n soju agbegbe naa se so, oni ohun ri gbo wi pe awon omo ologun Naijeria pada juba ehoro nigba ti agbara won ko ka awon omo Boko Haram ni agbegbe naa eleyii to mu isele naa buru jojo .

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment