Awọn kan ti n
gbiyanju lati se alaye itunmọ Yoruba leyin atotonu awon onimọ kan ti won gba wi
pe ohun to fẹ to jin bi omi okun ni Yoruba jẹ eleyii ti ko se e tupalẹ tan
raurau. Gege bi alaye won, wọn gba wi pe Yoruba rekọja èdè lasan bakan naa ni a
ko le duro lori alaye wi pe ẹ̀yà awon eniyan kan ti won gbe ni iwo-oorun Afirika
ni Yoruba jẹ nikan.
Gege bi won ti se agbekale rẹ ninu Jọna tuntun
Imọ Ẹ̀dá Ede (Linguistics) ati Orirun Awon Ohun Elo Eniyan Dudu ti awon onise
alakada ti ile adulawo ti odun 2014 gbe jade, won ni Ọgbọ́n ni Yoruba, kosi si
eda eniyan kan laye to si le gbon tan (Eyi tunmo si wi pe kosi eniyan kan to le
gbọ Yoruba tan). Idi ni yii ti won fi se apere YORUBA gege bi ohun to fẹ to si
tun jin bi omi okun. Sebi ohun to jọra lafi n wera won, epo epa lo jo poosi
eliri. Bi eniyan ba si fi ori ologini se apejuwe amotekun a ko le so wi pe eni
bee ko ri sọ.
Kosi eda eniyan
kan laye ti yoo gbo ede Yoruba de oju ami ti ko ni logbon lori, yala ninu ọ̀rọ̀
siso, ati bi eniyan se n wu iwa lawujo. Won fi idi re mule wi pe ogbon ni
Yoruba, bi eniyan ba gbọ ogidi Yoruba, ọgbọn ati laakaye ko le jina si iru eni
bẹẹ rara.
![]() |
Awon Akekoo Ede Yoruba |
Ninu afikun
alaye won, pupo awon oyinbo alawo funfun ti won wa si ile Adulawo lati wa ko
ede Yoruba kii se ede gan-angan ni larija ohun ti won wa n ko bi ko se ogbon ati
laakaye to farasin sinu ede, asa ati agbara to wa ninu esin abalaye iran
Yoruba. Eyi wa lara ohun to mu awon eya yoku maa se iba fun Yoruba lagbo oselu.
Yoruba le duro ki inu won loso. Yoruba le so wi pe “beeni” ki beeni si ni itunmo
bi ogun bi ọgbọ̀n. Yoruba le saleye oro siwaju ki akawe oro won si maa dori ko
ona eyin. Yoruba le dajọ iku eniyan ni iwaju eni ọrọ kan kii eni na si sebi won
fe fi oun joba ni.
Yoruba le ni
‘aye n tele Lagbaja’. Iru oro bayii le mu ki lagbaja bu sekun.
Yoruba tun le ni
‘aye ti pada leyin Lagbaja’. Eyi ko tunmo si wi pe ki lagbaja o maa rerin tabi ko
maa dunnu. Fun eni oro ba ye, o ye ko tun bu sekun peregede ni. Yoruba lagbara
pupo!
Ohun to wa lokan
mi ti mo fe so lonii ko ni yii, boya ti aye ba gba mi lojo mii maa tenubo awon
abajade iwadii awon onise alakada lorisirisi nipa agbara ti Edua Oke ko sinu
ogbon ti won pe ni YORUBA.
E je ki n tun yabara si apa ibo mii. Ogunjo osu
keji odun 1947 ni won bi John C. Maxwell ni Michigan to wa ni ilu Amerika. Pupo
ninu ibere pepe igbe aye re lo fi sise gege bi alufa adari ijo Oluwa ko to wa
di wi pe o di onkowe ati oludanileko ita gbangban. Die lara awon iwe olokiki to
ti ko ni 21 Irrefutable Laws of Leadership, The 21 Indispensable Qualities of a
Leader, Becoming the Person Other Will
Want to Follow ati bee bee lo.
Lara oro John Maxwell niyii :
“Asaaju je opomulero fun ogbon tabi agbara to gbe isọwọ awon eniyan kan, ile ise, egbe tabi ilu kan duro. Niwon igba ti irufe asaaju bee ba kuna ninu ojuse re, kosi bi ogbon tabi agbara to gbe ile ise, egbe tabi ilu naa duro ti wu ko lagbara to, opomulero naa yo ye lule ti gbogbo re yo si fonka yangayanga ayafi ti iranlowo ba dide ko to di wi pe oro bo sori.”
John Maxwell je
okan lara awon ọlọgbọn aye, bakan naa oun ni enikan ti won gba gege bi ọga
yan-anyan oluko nipa idanilekọ imo-isakoso, adari tabi asaaju. John Maxwell de
ipo yii latari imo ati iriri re eleyii to fihan ninu awon iwe re gbogbo to ti ko sita fun awon eniyan
lagbaye. Awon oro John Maxwell ti doosa ajiki, nitori awon oro re won kii tase
tabi kuna nipa oye re nipa imo isakoso
tabi adari.
Gege bi alaye
John Maxwell, o ni ko si bi ogbon ti wule ko lekenka to, ti asaaju to gbe ogbon naa ro ba kuna ninu ojuse re, dandan
ni ki ogbon naa di omugo eleyii ti abajade re ko ni dara rara.
Bi o tile je wi
pe aimoye awon agbalagba ma-je-o-baje ni won ti gbiyanju lati pari ija agba to
wa laarin Alaafin Oyo, Oba Lamide Adeyemi ati Ooni ti ile Ife, Oba Okunade Sijuwade sibesibe won gbo ni ko si eyi to gba ninu awon mejeeji.
Ohun to faja naa
ni bi Alaafin se n wi pe oun ni ojulowo Omo Odua kii se Ooni, ati wi pe ohun ni
asaaju gbogbo Yoruba ni tile-toko. Ooni Ile Ife ni Ife ni orirun gbogbo Yoruba
pata, ati wi pe ibi taa ba pe lori a kii fibe tele laelae. Ife ni iran Yoruba
ti se wa, ibe naa si ni ade Odudua wa titi di oni.
Lara awon to ti
da si oro naa ni Ogbeni Rauf Aregbesola. Bi o tile je wi pe ko si awuyewuye kankan
to jeyo mo nipa rugudu aarin won, sugbon o ye gbogbo wa wi pe kaka ki kinihun
se akapo ekun, onikaluku o se ode re lotooto ni. Nigba ti awon agba ile Yoruba
meji to ye ki won je opomulero ba n ba ara won takangbon kini yoo sele si okiki
iyi ati eye Yoruba to ti kari aye?
![]() |
Alaafin n fi oruko sile gege bi omo egbe A.P.C |
Sugbon pelu bi
nnkan se n lo lagbo oselu bayii, oseese ki wahala tun sele laaarin awon oba
mejeeji yii eleyii to le mu ifaseyin tabi tabuku Yoruba.
![]() |
Ninu Ogba Ile Iwe O.A.U Nibi Ti Awon Agba Ile Yoruba Ti Pejo Fi Ontelu Jonathan Gege Aare 2015 |
Omo egbe A.P.C
ni Alaafin Oyo, sebi gbogbo yin le mo igba ti baba lo fi oruko sile. Bi Ooni ko
ti le fi oruko sile bi omo egbe PDP, kosi eni ti oro ko ye wi pe imule egbe
alaburada ni Ooni ti ile Ife je. Ooni yii kan naa lo lewaju awon agbaagba
Yoruba ti won fi onte lu Aare Goodluck Jonathan gege bi eni to pegede lati di
Aare lodun 2015.
Oro oselu to fe
pin, tabi ki n so wi pe to ti pin awon asaaju ile Yoruba si meji yii, se ko ni se
akogba fun iran Yoruba?
Ohun to daju ni
wi pe egbe PDP ko ni wonkun, A.P.C naa ko ni gba laabo. Kaka ki eku ma je sese,
gbogbo wọn o fi sawadanu ni oro ibo odun 2015 je. To ba wa ri bee, se ajosepo
to wa laarin Alaafin ati Ooni yoo dan moran ni tabi yoo tun bo buru jai.
Mo toro gafara
lati pada si ori oro John Maxwell, okan pataki ninu awon ologbon aye leekan si,
pelu oro re ni i si maa fi kadi oro mi.
“Asaaju je opomulero fun ogbon tabi agbara to gbe isowo awon eniyan kan, ile ise, egbe tabi ilu kan duro. Niwon igba ti irufe asaaju bee ba kuna ninu ojuse re, kosi bi ogbon tabi agbara to gbe ile ise, egbe tabi ilu duro ti wu ko lagbara to, opomulero naa yo ye lule ti gbogbo re yo si fonka yangayanga ayafi ti iranlowo ba dide ko to di wi pe oro bo sori.” John Maxwell
Ikini:
Mo n fi asiko
yii kii Alfa Salami (Sheu Aseyori) ku imurasile odun tuntun to n bo lona. Fun
eto adura lorisirisi ati iwosan ara (eye diseases and stroke) e kan si AlfaSalami, eniyan Olorun tooto lori number yii: +2347065865035
0 comments:
Post a Comment