Smiley face

Won Ti Ri 'Sanyeri' Tuntun Ni Ilu China


Oro naa jo bi awada ni sugbon enikankan ko le rerin nigba oro naa sele.

Okunrin omo ile China kan to n se ise ni ile ise ti won ti n se aso lo sadeede fi orun ha si aarin okan lara awon irinse won nigba ise n lo lowo ni Zhejiang.

Fun nnkan bi wakati bi meta, won o ko ri 'Ogbeni Sanyeri' yii fayo nibi to forun ha si. Awon osise panapana lo pada wa ran won lowo nigba ti agbara won ko ka mo.

Won ti gbe okunrin naa lo si ile iwosan bayii nibi ti o ti n gba itoju lowolowo.

Erin ayitakiti ni awon osise ile ise naa fi okunrin yii rin nikete ti won gbe lo si ile iwosan tan. Won ni iran ni sugomu ara re n wo lo nigba ti ise nlo lowo, ko si mo igba ti gaga-irin meji to ye ko mu owu dani fi pade moo lorun.

Ki Olorun ba wa fun Mr Sanyeri lalaafia. Erkk
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment