Smiley face

Iku Fomida

Ojo oni dara fun mi. Oni ojo ibi mi. Eniyan le dupe to ba ranti ore, ko si bi ore ti wu le ko pe to, a fi asiere eniyan nikan ni o gbagbe ohun a se fun lana.

Awon Yoruba bo, won ni iku loni oro(wealth) lola, se iku oni le je ki eniiyan joro ola ni?

Nnkan bi ago meta ni ojo naa. Orun(sun) mbe loju orun(sky) sugbon ki i se eyi ti n tani leyin orun(neck). Ategun n fe igi ege ti won dako re segbe ile, bee lawon irawe to ti jabo sile to ti gbe n yokiti lo bi ategun se n fe yee.

Mo duro siwaju ile wi pe ki n fo awon abo ti mo fi jeun. Bi o tile ye mi wi pe ita gboro lowo taa wa yii. Ita gboro sugbon odede ni mo wa, eniyan ki i si wa nile re ko forun ro.


Awon omo elegbe okunkun ni won ba ara won ja, won si ti mu awon meji ninu won bale. Ara n kan onikaluku won, won soro bi ageku ejo, won si setan ati gbesan lai ko ohunkohun ti yoo na won. Ita gbe furufuru, ofon o firu lugba, onikaluku mbe ni yara re.

Ibi ayeye olojoibi kan ti won se ni igboro lemi lo. Awuyewuye wahala won ti won fa ni o je a le se faaji doba ti onikaluku fi fonka.


Ti mo fi dele loja naa boya ni mo pade eniyan meji lona. Bi ajeji gan-an ba wo inu ogba, ko niilo ki baba alawo difa fun un ko to mo wi pe ewu mbe loko longe.

Ki i se wi pe mo loso bi eni fe se igbonse, ori inaro ni mo wa, mo yatan, mo si te loole ti mo n fo awon abo mi. Boya ni mo ti i fo to abo meji.

Nibi mo wa, laaarin ese mi meji ni mo ti ri isowo awon eniyan kan ti won n bo leyin mi, won to le ara won bi omo ile iwe lori ila, won weri-wenu bi awon ara Ilorin. Alafo die lasan ni won fi sile nibi eyin oju won lati le ri ran. Awon wo leyii? Mo siri pake, moo boju weyin.


Ala ni mo ko sebi mo n la, ake, ibon, ada, akoro bi eyi ti won fi ka koko, pelu ogun orisiirisii ni won fi korun. Gbogbo won pata lo fi nnkan boju. Aya mi ja, gbogbo ara mi si domi. Mi o le lo iwaju, bee ni mo le pada seyin. Ti mo ba ni ki n salo ibon mbe lowo won. Iye mi ra patapata, mi o mo ohun mo le se. Tomode ba de ibi eru, dandan ni keru o ba.

Mi o lugbade awon omo elegbe okunkun ri, igba akoko re, eru iku ba mi ko maa je wi pe ibi ti n pari e si niyi. Won ko fenu soro simi, eyi to le iwaju ninu won lo sewo si mi pe ki n maa bo.


Atose ati keinkein atabo ti mbe lowo mi ni mo n lo soo bi eni ogun ti mu. Won ni ki n ju ohun mo ko dani sile nigba mo sun mo won, ori iduro ni mo ti dawon si le. Ki n to mo ohun to n sele, okan ti re mi nifase lateyin, mo nale gbi bi igba ti ogiri alapa wo lule. Won tu fa mi dide, igbarun ati igbati tun pade loju mi lojiji.


Owo ti won fi n gba mi loju run fun ogidi igbo. Iberu ki won mo sa mi lada tabi yin mi nibon o je kokan mi tile wa nibi igbarun ati ifoti ti won fun mi boya o n dun mi. Igba to ya die ti won ti din dundu iya fun mi.

Okan ninu won bere wi pe segbe okunkun alatako ni mo wa. Mo ni emi ki i se elegbe okunkun wi pe believe lemi.

Igba o tun ya ni o n wo mi niran, won se akiyesimi boya won sebi mo ni itu kan ti mo fe pa. Ati wi pe irisii mi n fu won lara. Nitori mo ga niwon ese bata mefa ati die, mo si je enikan to sanngun pelu irisii mi.


Igba o tun ya won ni se mo mo ibi ti awon elegbe alatako awon n gbe ni agbegbe mi tabi won ni orebinrin kan ti mo mo. Mo wi fun won wi pe mi o mo ohunkohun.


Won tun san mi nigbati olooyi moo mu mora, bi mi o tile mu mora, kini mo tun fe se? Iya mi o si nitosi, awon ti won yoju loju ferese o le jade gba mi le, awon eso alaabo ile iwe ti kari bonu, ayafi Olorun nikan lo le saanu mi. Eru ki won saa ma sa mi lada tabi yin mi nibon lo n ba mi pelu awon ohun ija oloro ti won ko dani.

Ibi eru ti wa ba mi ju ni igba ti won ki n maa niso ninu igbo, ona tooro kan la mori gba lese o gbeji. Won ni ki maa lo niwaju awon si n bo leyin. Mi o kaye won leni-eji sugbon won yoo to bi merindillogun tabi ju be lo. Bi mo se n lo niwaju won lokan mi n lu ki-ki-ki-ki.


Bakan naa ni mo n ro ko ma je wi pe fon fe yin mi nibon tabi sa mi lada lati eyin. Mi o le boju wehin wo ohun ti won fe se, bee naa ni mi o le duro wi pe mi o lo mo.

Igba to ya ni won ni ki n duro, gbogbo ara mi ti domi, owo mi ti tutu bi eja inu yinyin, ori mi ti fuye gee bi igba wara, okan mi n lu kikiki bi eni won ti gbe obe le lorun.


Bi aye ni mo wa bi orun ni mi o le so mi. Ete mi ti n gbon pepe bi faanu Taiwan ti igba ti lo lori re. Ito nikan loku ti mi o ti to sara.

Gbogbo won duro lo leba ona, won si ni ki n pada. Mo duro mi o le lo, mo n wo won loju. Igba to ya ni mo ta kiji, won ye fun mi lona, tori ibi ati n bo naa ni ma pada si, tooro si ni ona ohun.


Won ya die fun mi sinu igbo ki n le ri ona gba lo. Bi mo se n lo ni mo n duro siwaju okookan won ti mo se n 'tankiu' mi o le sare koja, bee naa ni mi o fe rindin ju ki won maa lo yi okan won pada.


Mo ko ja won siwaju die, bee lokan gbera so ninu won to n sare bo lodo mi. Mo gburo ese ni mo ba duro, odo mi ni mo sebi o tile n bo ni a fi bo se ya mi koja. Iwaju ile ti won ti ri mi lopada si. Igba o de be o foju wo ayika, kori nnkan, bee ni o bere nnkankan lowo mi.


Oni yara mi da wi pe ohun o ti mi mole, igba o tun ya lonii ki n wole ki n ti ilekun mori. Gbogbo bi ti n wi 'yesa yesa' naa ni mo n wi. Bo tun se jade lo nu -un.

Ojo keta tabi merin si gba naa ni iya mi pe mi lati bere alaafia mi. Mo ni alaafia ni mo wa. Iya mi ni awon la ala kan si mi o. Won ni sugbon awon ti gbadura fun mi, awon si gba wi pe adura naa ti se, won si so fun mi ki maa sora.

Mo beere lowo iya mi wi pe iru ala wo ni. Iya mi so wi pe ohun ri mi laarin awon omo eleegbe okunkun. Mi o so ohun o sele fun iya mi, mo kan dupe lowo won naa ni.

Mi o mo ohun ti won fe lo mumi se ninu igbo, sugbon ohun meji loseese koje, yala ki won semi lese tabi ki won pami tabi ki won ni darapo mo awon ni dandan.

Bi o tile je wi pe o ti to bi odun merin seyin, sibesibe mi o gbagbe ore Oluwa laye mi. Edumare lo komi yoo, iku ti mba ku fomida.


Olayemi Olatilewa
@dakewi

Sent from my BlackBerry wireless device from MTN

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment